1 Chronicles 2:1-15

Àwọn ọmọ Israẹli

1 aÀwọn wọ̀nyí ni àwọn ọmọ Israẹli. Reubeni, Simeoni, Lefi, Juda, Isakari, Sebuluni, 2Dani, Josẹfu, Benjamini; Naftali, Gadi: àti Aṣeri.

Juda

Àwọn ọmọ Hesroni

3 bÀwọn ọmọ Juda:
Eri, Onani àti Ṣela, àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí ni wọ́n bí fún un láti ọ̀dọ̀ arábìnrin Kenaani, ọmọbìnrin Ṣua.
Eri àkọ́bí Juda, ó sì burú ní ojú Olúwa; Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa sì pa á.
4Tamari, aya ọmọbìnrin Juda, ó sì bí Peresi àti Sera sì ní ọmọ márùn-ún ní àpapọ̀.

5 cÀwọn ọmọ Peresi:
Hesroni àti Hamulu.
6Àwọn ọmọ Sera:
Simri, Etani, Hemani, Kalkoli àti Dara, gbogbo wọn jẹ́ márùn-ún.
7Àwọn ọmọ Karmi:
Akani, ẹni tí ó mú ìyọnu wá sórí Israẹli nípa ẹ̀ṣẹ̀ ìfibú lórí mímú ohun ìyàsọ́tọ̀.
8Àwọn ọmọ Etani:
Asariah.
9Àwọn ọmọ tí a bí fún Hesroni ni:
Jerahmeeli, Ramu àti Kalebu.

Láti ọ̀dọ̀ Ramu ọmọ Hesroni

10Ramu sì ni baba Amminadabu,
àti Amminadabu baba Nahiṣoni olórí àwọn ènìyàn Juda.
11Nahiṣoni sì ni baba Salmoni,
Salmoni ni baba Boasi,
12Boasi baba Obedi
àti Obedi baba Jese.

13Jese sì ni baba
Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́kejì sì ni Abinadabu,
ẹlẹ́kẹta ni Ṣimea,
14Ẹlẹ́kẹrin Netaneli,
ẹlẹ́karùnún Raddai,
15ẹlẹ́kẹfà Osemu
àti ẹlẹ́keje Dafidi.
Copyright information for YorBMYO